Johanu 4:15
John 4:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”
John 4:15 in English
John 4:15 · Berean Standard Bible
The woman said to Him, “Sir, give me this water so that I will not get thirsty and have to keep coming here to draw water.”
Context
13Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́. 14Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.” 15Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.” 16Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.” 17Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.”
Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.