Native Bible

John 4:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

John 4:14 in English

John 4:14 · Berean Standard Bible

But whoever drinks the water I give him will never thirst. Indeed, the water I give him will become in him a fount of water springing up to eternal life.”

Context

12Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?” 13Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́. 14Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.” 15Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.” 16Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.