Native Bible

John 21:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀.

John 21:2 in English

John 21:2 · Berean Standard Bible

Simon Peter, Thomas called Didymus,* Nathanael from Cana in Galilee, the sons of Zebedee, and two other disciples were together.

Context

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn. 2Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀. 3Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun. 4Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.