Native Bible

John 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”

John 2:5 in English

John 2:5 · Berean Standard Bible

His mother said to the servants, “Do whatever He tells you.”

Context

3Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.” 4Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.” 5Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.” 6Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá. 7Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.