Native Bible

John 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.

John 2:7 in English

John 2:7 · Berean Standard Bible

Jesus told the servants, “Fill the jars with water.” So they filled them to the brim.

Context

5Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.” 6Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá. 7Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí. 8Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.” Wọ́n sì gbé e lọ; 9alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.