Johanu 18:6
John 18:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.
John 18:6 in English
John 18:6 · Berean Standard Bible
When Jesus said, “I am He,” they drew back and fell to the ground.
Context
4Nítorí náà bí Jesu ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni ẹyin ń wá?” 5Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jesu ti Nasareti.”
Jesu sì wí fún wọn pé, “Èmi nìyí.” (Àti Judasi ọ̀dàlẹ̀, dúró pẹ̀lú wọn). 6Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀. 7Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, “Ta ni ẹ ń wá?”
Wọ́n sì wí pé, “Jesu ti Nasareti.” 8Jesu dáhùn pé, “Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí. Ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.