Johanu 12:38
John 12:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́ Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”
John 12:38 in English
John 12:38 · Berean Standard Bible
This was to fulfill the word of Isaiah the prophet: “Lord, who has believed our message? And to whom has the arm of the Lord been revealed?”*
Context
36Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn. 37Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́. 38Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé,
“Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́
Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?” 39Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé, 40“Ó ti fọ́ wọn lójú,
Ó sì ti sé àyà wọn le;
kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,
kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,
kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.