Johanu 12:27
John 12:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kín ni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí.
John 12:27 in English
John 12:27 · Berean Standard Bible
Now My soul is troubled, and what shall I say? ‘Father, save Me from this hour’? No, it is for this purpose that I have come to this hour.
Context
25Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. 26Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn, àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún. 27“Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kín ni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí. 28Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!”
Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!” 29Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, “Àrá ń sán.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Angẹli kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.