Native Bible

John 12:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, “Àrá ń sán.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Angẹli kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”

John 12:29 in English

John 12:29 · Berean Standard Bible

The crowd standing there heard it and said that it had thundered. Others said that an angel had spoken to Him.

Context

27“Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kín ni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí. 28Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!” Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!” 29Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, “Àrá ń sán.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Angẹli kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.” 30Jesu sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín. 31Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.