Johanu 12:26
John 12:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn, àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.
John 12:26 in English
John 12:26 · Berean Standard Bible
If anyone serves Me, he must follow Me; and where I am, My servant will be as well. If anyone serves Me, the Father will honor him.
Context
24Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 25Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. 26Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn, àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún. 27“Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kín ni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí. 28Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!”
Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.