Johanu 12:24
John 12:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso.
John 12:24 in English
John 12:24 · Berean Standard Bible
Truly, truly, I tell you, unless a kernel of wheat falls to the ground and dies, it remains only a seed; but if it dies, it bears much fruit.
Context
22Filipi wá, ó sì sọ fún Anderu; Anderu àti Filipi wá, wọ́n sì sọ fún Jesu. 23Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ Ènìyàn lógo. 24Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 25Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. 26Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn, àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.