Native Bible

John 12:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ Ènìyàn lógo.

John 12:23 in English

John 12:23 · Berean Standard Bible

But Jesus replied, “The hour has come for the Son of Man to be glorified.

Context

21Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Filipi wá, ẹni tí í ṣe ará Betisaida tí Galili, wọ́n sì ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jesu!” 22Filipi wá, ó sì sọ fún Anderu; Anderu àti Filipi wá, wọ́n sì sọ fún Jesu. 23Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ Ènìyàn lógo. 24Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 25Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.