Johanu 11:21
John 11:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.
John 11:21 in English
John 11:21 · Berean Standard Bible
Martha said to Jesus, “Lord, if You had been here, my brother would not have died.
Context
19Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. 20Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé. 21Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. 22Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.” 23Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.