Johanu 10:23
John 10:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni.
John 10:23 in English
John 10:23 · Berean Standard Bible
and Jesus was walking in the temple courts * in Solomon’s Colonnade.
Context
21Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?” 22Àkókò náà sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jerusalẹmu, ni ìgbà òtútù. 23Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni. 24Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kristi náà, wí fún wa gbangba.” 25Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.