Johanu 10:15
John 10:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba, mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.
John 10:15 in English
John 10:15 · Berean Standard Bible
just as the Father knows Me and I know the Father. And I lay down My life for the sheep.
Context
13Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn. 14“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba, mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.