Johanu 10:14
John 10:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí.
John 10:14 in English
John 10:14 · Berean Standard Bible
I am the good shepherd. I know My sheep and My sheep know Me,
Context
12Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn. 14“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba, mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.