Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Olúwa wọn fẹ́.

Jeremiah 8:7 in English

Jeremiah 8:7 · Berean Standard Bible

Even the stork in the sky knows her appointed seasons. The turtledove, the swift, and the thrush * keep their time of migration, but My people do not know the requirements of the LORD.

Context

5Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti yípadà. 6Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun. 7Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Olúwa wọn fẹ́. 8“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n, nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn. 9Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn. Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa, irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.