Jeremiah 8:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
Jeremiah 8:6 in English
Jeremiah 8:6 · Berean Standard Bible
I have listened and heard; they do not speak what is right. No one repents of his wickedness, asking, ‘What have I done?’ Everyone has pursued his own course like a horse charging into battle.
Context
4“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí?
Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí? 5Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀?
Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?
Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn;
wọ́n kọ̀ láti yípadà. 6Mo ti fetísílẹ̀ dáradára,
wọn kò sọ ohun tí ó tọ́.
Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,
kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?”
Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun. 7Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run
mọ ìgbà tirẹ̀,
àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé
mọ àkókò ìṣípò padà wọn.
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ
ohun tí Olúwa wọn fẹ́. 8“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,
nítorí a ní òfin Olúwa,”
nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé
ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.