Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ẹ lọ nísinsin yìí sí Ṣilo níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Israẹli tí í ṣe ènìyàn mi.

Jeremiah 7:12 in English

Jeremiah 7:12 · Berean Standard Bible

But go now to the place in Shiloh where I first made a dwelling for My Name, and see what I did to it because of the wickedness of My people Israel.

Context

10Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” àwa yè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra wọ̀nyí bí? 11Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí. 12“ ‘Ẹ lọ nísinsin yìí sí Ṣilo níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Israẹli tí í ṣe ènìyàn mi. 13Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn. 14Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí Ṣilo sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé tẹmpili nínú èyí tí ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ààyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.