Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn.

Jeremiah 7:13 in English

Jeremiah 7:13 · Berean Standard Bible

And now, because you have done all these things, declares the LORD, and because I have spoken to you again and again * but you would not listen, and I have called to you but you would not answer,

Context

11Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́ṣà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí. 12“ ‘Ẹ lọ nísinsin yìí sí Ṣilo níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Israẹli tí í ṣe ènìyàn mi. 13Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn. 14Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí Ṣilo sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé tẹmpili nínú èyí tí ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ààyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín. 15Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Efraimu.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.