Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá, tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré? Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ọrẹ yín kò sì wù mí.”

Jeremiah 6:20 in English

Jeremiah 6:20 · Berean Standard Bible

What use to Me is frankincense from Sheba or sweet cane from a distant land? Your burnt offerings are not acceptable; your sacrifices do not please Me.”

Context

18Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè; kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn. 19Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, èso ìrò inú wọn, nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀. 20Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá, tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré? Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ọrẹ yín kò sì wù mí.” 21Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Àwọn baba àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n, àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.” 22Báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá, a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde láti òpin ayé wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.