Jeremiah 6:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè; kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.
Jeremiah 6:18 in English
Jeremiah 6:18 · Berean Standard Bible
Therefore hear, O nations, and learn, O congregations, what will happen to them.
Context
16Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò,
ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́,
ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ,
ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’ 17Èmi yan olùṣọ́ fún un yín,
mo sì wí pé:
‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’
ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’ 18Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;
kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí,
ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn. 19Gbọ́, ìwọ ayé!
Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,
èso ìrò inú wọn,
nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi,
wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀. 20Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá,
tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré?
Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà,
ọrẹ yín kò sì wù mí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.