Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra.

Jeremiah 52:22 in English

Jeremiah 52:22 · Berean Standard Bible

The bronze capital atop one pillar was five cubits high,* with a network of bronze pomegranates all around. The second pillar, with its pomegranates, was similar.

Context

20Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ. 21Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́n yìí ni ga ní ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún; okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá sì yí i ká. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú. 22Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra. 23Pomegiranate mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranate sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan. 24Balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ mu Seraiah olórí àwọn àlùfáà àti Sefaniah àlùfáà kejì àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.