Jeremiah 52:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe.
Jeremiah 52:2 in English
Jeremiah 52:2 · Berean Standard Bible
And Zedekiah did evil in the sight of the LORD, just as Jehoiakim had done.
Context
1Sedekiah jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọ Jeremiah; láti Libina ló ti wá. 2Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe. 3Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu àti Juda àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀.
Sedekiah ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli. 4Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ti Sedekiah tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá Nebukadnessari ọba Babeli sì lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.