Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàndínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu.

Jeremiah 52:12 in English

Jeremiah 52:12 · Berean Standard Bible

On the tenth day of the fifth month, in the nineteenth year of Nebuchadnezzar’s reign over Babylon, Nebuzaradan captain of the guard, a servant of the king of Babylon, entered Jerusalem.

Context

10Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda. 11Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. 12Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàndínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu. 13Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńlá ńlá. 14Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.