Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńlá ńlá.

Jeremiah 52:13 in English

Jeremiah 52:13 · Berean Standard Bible

He burned down the house of the LORD, the royal palace, and all the houses of Jerusalem—every significant building.

Context

11Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. 12Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàndínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu. 13Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńlá ńlá. 14Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 15Nebusaradani balógun ìṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.