Jeremiah 51:50
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró. Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè, ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”
Jeremiah 51:50 in English
Jeremiah 51:50 · Berean Standard Bible
You who have escaped the sword, depart and do not linger! Remember the LORD from far away, and let Jerusalem come to mind.”
Context
48Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,
yóò sì kọrin lórí Babeli:
nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,”
ni Olúwa wí. 49“Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli,
gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli. 50Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró.
Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè,
ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.” 51“Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn:
ìtìjú ti bò wá lójú
nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.” 52“Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
“tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀,
àti àwọn tí ó gbọgbẹ́
yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.