Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀, o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.

Jeremiah 51:15 in English

Jeremiah 51:15 · Berean Standard Bible

The LORD made the earth by His power; He established the world by His wisdom and stretched out the heavens by His understanding.

Context

13Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò! 14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀, Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú, wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ. 15“Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀, o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀. 16Nígbà tí ará omi ọ̀run hó ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé. Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀. 17“Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ tí kò sì ní ìmọ̀, olúkúlùkù alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀. Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn; wọn kò ní èémí nínú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.