Jeremiah 51:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀, Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú, wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ.
Jeremiah 51:14 in English
Jeremiah 51:14 · Berean Standard Bible
The LORD of Hosts has sworn by Himself: “Surely I will fill you up with men as with locusts, and they will shout in triumph over you.”
Context
12Gbé àsíá sókè sí odi Babeli!
Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí,
ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri,
ẹ ṣètò àwọn tí yóò sá pamọ́
Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde,
òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli. 13Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀,
tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé,
àní àsìkò láti ké ọ kúrò! 14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀,
Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú,
wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ. 15“Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀,
o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,
o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀. 16Nígbà tí ará omi ọ̀run hó
ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé.
Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,
ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.