Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo.

Jeremiah 50:9 in English

Jeremiah 50:9 · Berean Standard Bible

For behold, I stir up and bring against Babylon an assembly of great nations from the land of the north. They will line up against her; from the north she will be captured. Their arrows will be like skilled warriors who do not return empty-handed.

Context

7Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’ 8“Jáde kúrò ní Babeli, ẹ fi ilẹ̀ àwọn ará Kaldea sílẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ bí òbúkọ níwájú agbo ẹran. 9Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo. 10A ó dààmú Babeli, gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn ṣẹ,” ni Olúwa wí. 11“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀, ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù, ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.