Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Jáde kúrò ní Babeli, ẹ fi ilẹ̀ àwọn ará Kaldea sílẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ bí òbúkọ níwájú agbo ẹran.

Jeremiah 50:8 in English

Jeremiah 50:8 · Berean Standard Bible

Flee from the midst of Babylon; depart from the land of the Chaldeans; be like the he-goats that lead the flock.

Context

6“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà, wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré, wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn. 7Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’ 8“Jáde kúrò ní Babeli, ẹ fi ilẹ̀ àwọn ará Kaldea sílẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ bí òbúkọ níwájú agbo ẹran. 9Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo. 10A ó dààmú Babeli, gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn ṣẹ,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.