Jeremiah 49:37
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn, àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn, Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn, àní, ìbínú gbígbóná mi,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.
Jeremiah 49:37 in English
Jeremiah 49:37 · Berean Standard Bible
So I will shatter Elam before their foes, before those who seek their lives. I will bring disaster upon them, even My fierce anger,” declares the LORD. “I will send out the sword after them until I finish them off.
Context
35Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ:
“Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu,
ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára. 36Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin
àgbáyé lòdì sí Elamu.
Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé,
kò sí orílẹ̀-èdè
tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ. 37Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn,
àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn,
Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn,
àní, ìbínú gbígbóná mi,”
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
“Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn. 38Èmi yóò sì gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu,
èmí yóò sì pa ọba wọn àti ìjòyè wọn run,”
báyìí ni Olúwa wí. 39“Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ
Elamu padà láìpẹ́ ọjọ́,”
báyìí ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.