Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa Ammoni. Báyìí ni Olúwa wí, “Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin? Israẹli kò ha ní àrólé bí? Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?

Jeremiah 49:1 in English

Jeremiah 49:1 · Berean Standard Bible

Concerning the Ammonites, this is what the LORD says: “Has Israel no sons? Is he without heir? Why then has Milcom * taken possession of Gad? Why have his people settled in their cities?

Context

1Nípa Ammoni. Báyìí ni Olúwa wí, “Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin? Israẹli kò ha ní àrólé bí? Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀? 2Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí; “nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun ní Rabba tí Ammoni; yóò sì di òkìtì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná. Nígbà náà ni Israẹli yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,” ni Olúwa wí. 3“Hu, ìwọ Heṣboni, nítorí Ai tí rún! Kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba! Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà, nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.