Jeremiah 48:31
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Moabu fún àwọn ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara, mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
Jeremiah 48:31 in English
Jeremiah 48:31 · Berean Standard Bible
Therefore I will wail for Moab; I will cry out for all of Moab; I will moan for the men of Kir-heres.*
Context
29“A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu:
àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀
àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀. 30Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni Olúwa wí,
“ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan. 31Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Moabu
fún àwọn ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara,
mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti. 32Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún
ìwọ àjàrà Sibma.
Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun,
wọn dé Òkun Jaseri.
Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ,
ìkórè èso àjàrà rẹ. 33Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò
nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu.
Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí;
kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà,
wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.