Jeremiah 47:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀. A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́; ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?
Jeremiah 47:5 in English
Jeremiah 47:5 · Berean Standard Bible
The people of Gaza will shave their heads in mourning; Ashkelon will be silenced. O remnant of their valley,* how long will you gash yourself?
Context
3nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára
nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá
àti iye kẹ̀kẹ́ wọn.
Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;
ọwọ́ wọn yóò kákò. 4Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé
láti pa àwọn Filistini run,
kí a sì mú àwọn tí ó là
tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò.
Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run,
àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori. 5Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.
A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́;
ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,
ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó? 6“Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,
yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?
Padà sínú àkọ̀ rẹ;
sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’ 7Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi,
nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un,
nígbà tí ó ti pa á láṣẹ
láti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.