Jeremiah 46:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin, ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́. Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú, àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú; àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.
Jeremiah 46:9 in English
Jeremiah 46:9 · Berean Standard Bible
Advance, O horses! Race furiously, O chariots! Let the warriors come forth— Cush * and Put carrying their shields, men of Lydia drawing the bow.
Context
7“Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,
tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì? 8Ejibiti dìde bí odò náà,
bí omi odò tí ń ru.
Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’
Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run. 9Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,
ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.
Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,
àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú;
àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun. 10Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,
títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.
Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ
ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate. 11“Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,
ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.
Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,
kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.