Jeremiah 46:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ nítorí Memfisi yóò di ahoro a ó sì fi jóná, láìní olùgbé.
Jeremiah 46:19 in English
Jeremiah 46:19 · Berean Standard Bible
Pack your bags for exile, O daughter dwelling in Egypt! For Memphis will be laid waste, destroyed and uninhabited.
Context
17Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,
‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa,
ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’ 18“Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba,
ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“Nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti
gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé. 19Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti
pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ
nítorí Memfisi yóò di ahoro
a ó sì fi jóná, láìní olùgbé. 20“Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti
ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé,
ó dé láti àríwá. 21Àwọn jagunjagun rẹ̀
dàbí àbọ́pa akọ màlúù.
Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,
wọn ó sì jùmọ̀ sá,
wọn kò ní le dúró,
nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn
àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.