Jeremiah 43:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Baruku, ọmọ Neriah, ni ó fi ọ̀rọ̀ sí ọ lẹ́nu sí wa, láti fà wá lé àwọn ará Babeli lọ́wọ́, láti pa wá àti láti kó wa ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.”
Jeremiah 43:3 in English
Jeremiah 43:3 · Berean Standard Bible
Rather, Baruch son of Neriah is inciting you against us to deliver us into the hands of the Chaldeans,* so that they may put us to death or exile us to Babylon!”
Context
1Nígbà tí Jeremiah parí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan. 2Asariah ọmọ Hoṣaiah àti Johanani ọmọ Karea, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremiah pé, “Ìwọ ń pa irọ́! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Ejibiti láti ṣàtìpó níbẹ̀.’ 3Ṣùgbọ́n Baruku, ọmọ Neriah, ni ó fi ọ̀rọ̀ sí ọ lẹ́nu sí wa, láti fà wá lé àwọn ará Babeli lọ́wọ́, láti pa wá àti láti kó wa ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.” 4Nítorí náà, Johanani ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Juda. 5Dípò bẹ́ẹ̀, Johanani ọmọ Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun sì ko àwọn àjẹkù Juda tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Juda láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.