Jeremiah 43:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dípò bẹ́ẹ̀, Johanani ọmọ Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun sì ko àwọn àjẹkù Juda tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Juda láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká.
Jeremiah 43:5 in English
Jeremiah 43:5 · Berean Standard Bible
Instead, Johanan son of Kareah and all the commanders of the forces took the whole remnant of Judah, those who had returned to the land of Judah from all the nations to which they had been scattered,
Context
3Ṣùgbọ́n Baruku, ọmọ Neriah, ni ó fi ọ̀rọ̀ sí ọ lẹ́nu sí wa, láti fà wá lé àwọn ará Babeli lọ́wọ́, láti pa wá àti láti kó wa ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.” 4Nítorí náà, Johanani ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Juda. 5Dípò bẹ́ẹ̀, Johanani ọmọ Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun sì ko àwọn àjẹkù Juda tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Juda láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká. 6Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusaradani balógun ẹ̀ṣọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, àti Jeremiah wòlíì náà àti Baruku ọmọ Neriah. 7Nítorí náà, wọn wọ Ejibiti pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Tafanesi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.