Jeremiah 41:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà.
Jeremiah 41:3 in English
Jeremiah 41:3 · Berean Standard Bible
Ishmael also killed all the Jews who were with Gedaliah at Mizpah, as well as the Chaldean * soldiers who were there.
Context
1Ní oṣù keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, àti àwọn ìjòyè ọba, àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu wá ní Mispa; níbẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ jẹun ní Mispa. 2Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. 3Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà. 4Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Gedaliah kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀, 5àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣekemu, Ṣilo àti Samaria, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n ṣá ara wọn lọ́gbẹ́, wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.