Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà.

Jeremiah 41:2 in English

Jeremiah 41:2 · Berean Standard Bible

Then Ishmael son of Nethaniah and the ten men who were with him got up and struck down Gedaliah son of Ahikam, the son of Shaphan, with the sword, killing the one whom the king of Babylon had appointed to govern the land.

Context

1Ní oṣù keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, àti àwọn ìjòyè ọba, àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu wá ní Mispa; níbẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ jẹun ní Mispa. 2Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. 3Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà. 4Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Gedaliah kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.