Jeremiah 4:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn, sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró. Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá, àní ìparun tí ó burú jọjọ.”
Jeremiah 4:6 in English
Jeremiah 4:6 · Berean Standard Bible
Raise a signal flag toward Zion. Seek refuge! Do not delay! For I am bringing disaster from the north, and terrible destruction.
Context
4Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa,
kọ ọkàn rẹ ní ilà,
ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu,
bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná,
nítorí ibi tí o ti ṣe
kì yóò sí ẹni tí yóò pa á. 5“Kéde ní Juda, kí o sì polongo ní Jerusalẹmu, kí o sì wí pé:
‘Fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀!’
Kí o sì kígbe:
‘Kó ara jọ pọ̀!
Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’ 6Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn,
sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró.
Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá,
àní ìparun tí ó burú jọjọ.” 7Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀,
apanirun orílẹ̀-èdè sì ti jáde.
Ó ti fi ààyè rẹ̀ sílẹ̀
láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́.
Ìlú rẹ yóò di ahoro
láìsí olùgbé. 8Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀
káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún,
nítorí ìbínú ńlá Olúwa
kò tí ì kúrò lórí wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.