Jeremiah 4:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa, kọ ọkàn rẹ ní ilà, ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná, nítorí ibi tí o ti ṣe kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.
Jeremiah 4:4 in English
Jeremiah 4:4 · Berean Standard Bible
Circumcise yourselves to the LORD, and remove the foreskins of your hearts, O men of Judah and people of Jerusalem. Otherwise, My wrath will break out like fire and burn with no one to extinguish it, because of your evil deeds.”
Context
2Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra.
Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ,
àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.” 3Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu:
“Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí,
kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún. 4Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa,
kọ ọkàn rẹ ní ilà,
ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu,
bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná,
nítorí ibi tí o ti ṣe
kì yóò sí ẹni tí yóò pa á. 5“Kéde ní Juda, kí o sì polongo ní Jerusalẹmu, kí o sì wí pé:
‘Fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀!’
Kí o sì kígbe:
‘Kó ara jọ pọ̀!
Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’ 6Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn,
sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró.
Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá,
àní ìparun tí ó burú jọjọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.