Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra. Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ, àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”

Jeremiah 4:2 in English

Jeremiah 4:2 · Berean Standard Bible

and if you can swear, ‘As surely as the LORD lives,’ in truth, in justice, and in righteousness, then the nations will be blessed by Him, and in Him they will glory.”

Context

1“Tí ìwọ yóò bá yí padà, ìwọ Israẹli, padà tọ̀ mí wá,” ni Olúwa wí. “Tí ìwọ yóò bá sì mú ìríra rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ kí ó sì rìn kiri. 2Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra. Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ, àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.” 3Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu: “Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí, kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún. 4Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa, kọ ọkàn rẹ ní ilà, ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná, nítorí ibi tí o ti ṣe kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.