Jeremiah 36:29
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.”
Jeremiah 36:29 in English
Jeremiah 36:29 · Berean Standard Bible
You are to proclaim concerning Jehoiakim king of Judah that this is what the LORD says: You have burned the scroll and said, ‘Why have you written on it that the king of Babylon would surely come and destroy this land and deprive it of man and beast?’
Context
27Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá: 28“Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná. 29Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.” 30Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí ní ti Jehoiakimu ọba Juda pé, Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru. 31Èmi ó sì jẹ òun àti irú-ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìyà nítorí àìṣedéédéé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn Juda, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.