Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá:

Jeremiah 36:27 in English

Jeremiah 36:27 · Berean Standard Bible

After the king had burned the scroll containing the words that Baruch had written at Jeremiah’s dictation, the word of the LORD came to Jeremiah:

Context

25Elnatani, Delaiah àti Gemariah sì bẹ ọba kí ó má ṣe fi ìwé kíká náà jóná, ṣùgbọ́n ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn. 26Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́. 27Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá: 28“Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná. 29Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.