Jeremiah 36:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”
Jeremiah 36:19 in English
Jeremiah 36:19 · Berean Standard Bible
Then the officials said to Baruch, “You and Jeremiah must hide yourselves and tell no one where you are.”
Context
17Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?” 18Baruku sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.” 19Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.” 20Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíká náà pamọ́ sí iyàrá Eliṣama akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí ọba. 21Ọba sì rán Jehudu láti lọ mú ìwé kíká náà wá, Jehudu sì mu jáde láti inú iyàrá Eliṣama akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.