Jeremiah 36:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?”
Jeremiah 36:17 in English
Jeremiah 36:17 · Berean Standard Bible
“Tell us now,” they asked Baruch, “how did you write all these words? Was it at Jeremiah’s dictation?”
Context
15Wọ́n sì wí fún pé, “Jókòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!”
Nígbà náà ni Baruku sì kà á ní etí wọn. 16Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan; wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù. Wọ́n sì wí fún Baruku pé, “Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba.” 17Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?” 18Baruku sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.” 19Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.