Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu.

Jeremiah 32:37 in English

Jeremiah 32:37 · Berean Standard Bible

I will surely gather My people from all the lands to which I have banished them in My furious anger and great wrath, and I will return them to this place and make them dwell in safety.

Context

35Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Baali ní àfonífojì Hinnomu láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rú ẹbọ sí Moleki. Èmi kò pàṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Juda dẹ́ṣẹ̀. 36“Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn ni à ó fi wọ́n fún ọba Babeli,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ nìyìí, 37Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu. 38Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 39Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.