Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o pàṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.

Jeremiah 32:23 in English

Jeremiah 32:23 · Berean Standard Bible

They came in and possessed it, but they did not obey Your voice or walk in Your law. They failed to perform all that You commanded them to do, and so You have brought upon them all this disaster.

Context

21O kó àwọn Israẹli ènìyàn rẹ jáde láti Ejibiti pẹ̀lú iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá. 22Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. 23Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o pàṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn. 24“Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe kórajọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kaldea tí ń gbóguntì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i. 25Síbẹ̀ a ó fi ìlú náà fún àwọn ará Babeli, ìwọ Olúwa Olódùmarè sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.